You’re invited to the 2024 Hepatitis B Foundation Gala on April 5, 2024 in Warrington, PA. Details here.

Yoruba

Káàbọ̀ sí Abala Yorùbá ti Ojúlé Wẹ́ẹ̀bù Àjọ Àrùn Ẹ̀dọ̀fóró B

Àrùn Ẹ̀dọ̀fóró B ni a mọ̀ bíi àrùn tó farapamọ́, àti wípé ọ̀pọ̀ ènìyàn kò tilẹ̀ mọ̀ wípé wọ́n ní àrùn náà. Ojúlé wẹ́ẹ̀bù yìí ní àlàyé nípa dídènà, àyẹ̀wò àti ìṣàkóso àrùn ẹ̀dọ̀fóró B. A rọ̀ ọ́ láti ṣàpínlò àlàyé yìí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ẹbí àti àwọn míràn ní agbègbè rẹ. Ìwọ̀nyí ni àwọn ohun pàtàkì láti rántí nípa àrùn ẹ̀dọ̀fóró B:

  • A kìí jogún àrùn ẹ̀dọ̀fóró B - kòkòrò kan ló ṣokùnfà. 
  • Àjẹsára kan wà tí yóò dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ àrùn ẹ̀dọ̀fóró B títí ayé. 
  • Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ kan tó rọrùn kan wà láti ṣàyẹ̀wò àrùn ẹ̀dọ̀fóró B. 
  • Àwọn àṣàyàn ìtọ́jú wà.

Àrùn Ẹ̀dọ̀fóró B jẹ́ Àìsàn Àgbáyé

Àrùn Ẹ̀dọ̀fóró B le ran ẹnikẹ́ni ní ọjọ́-orí tàbí ẹ̀yà, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn láti abala àgbáyé kan níbití àrùn ẹ̀dọ̀fóró B ti wọ́pọ̀ jù, bíi Asia, abala Afirika àtì South America, Eastern Europe, àtì Middle East, wà lábẹ́ ọ̀pọ̀ ewu láti ní àkóràn. Àrùn Ẹ̀dọ̀fóró B tún wọ́pọ̀ láàrín àwọn ará Amẹrika tí a bí (tàbí tí a bí àwọn òbí wọn) sí àwọn agbègbè wọ̀nyí.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù ènìyàn káàkiri àgbáyé ló ní àrùn ẹ̀dọ̀fóró B. Kódà ọ̀pọ̀ ènìyàn kò mọ̀ wípé wọ́n ní àrùn náà, kò sì ní àmì àrùn – ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nkan pàtàkì ni o gbọ́dọ̀ mọ̀. Ṣíṣe àyẹ̀wò fún àrùn ẹ̀dọ̀fóró B le dóòlà ẹ̀mí rẹ. Tí o bá mọ̀ wípé o ní àrùn ẹ̀dọ̀fóró B, o le ṣe àwọn ẹ̀yàn ìgbé ayé láti jẹ́ kí ẹ̀dọ̀ rẹ wà ní ìlera o sì le rí dókítà kan láti ṣàkóso kòkòrò náà kó sì dènà ìbàjẹ́ ẹ̀dọ̀fóró.

Àjọ Àrùn Ẹ̀dọ̀fóró B jẹ́ àjọ orílẹ̀-èdè kan tí kò sí fún èrè tó sì farajì láti wá ìwòsàn àti láti ṣèrànwọ́ mímú ìgbé ayé tó dára dàgbà fún gbogbo àwọn tó ní àrùn ẹ̀dọ̀fóró B káàkiri àgbáyé nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí, ẹ̀kọ́ àti sísọ̀rọ̀ fún àwọn aláìsàn.

Ìkọ̀sílẹ̀: Àlàyé tí a pèsè lórí ojúlé wẹ́ẹ̀bù yìí wà fún èrèdí ìkẹ́kọ̀ọ́ nìkan. Àjọ Àrùn Ẹ̀dọ̀fóró B kìíṣe ilé-ìwòsan. Jọ̀wọ́ bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ tàbí olùpèsè ìtọ́jú ìlera kan tó kọ́ṣẹ́mọṣẹ́ fún ìtọ́jú ìlera àdani àti ìmọ̀ràn.

Welcome to the Yoruba Chapter of the Hepatitis B Foundation Website

Hepatitis B is known as a silent disease, and most people don’t even know they are infected. This website contains information about preventing, diagnosing and managing hepatitis B. We encourage you to share this information with your friends, family and others in your community. Here are some important things to remember about hepatitis B:

  • Hepatitis B is not inherited - it is caused by a virus. 
  • There is a safe vaccine which will protect you from hepatitis B for life. 
  • There is a simple blood test to diagnose hepatitis B. 
  • There are treatment options.

Hepatitis B is a Global Disease

Hepatitis B can infect any person of any age or ethnicity, but people from parts of the world where hepatitis B is common, such as Asia, parts of Africa and South America, Eastern Europe, and the Middle East, are at much higher risk for getting infected. Hepatitis B is also common among Americans who were born (or whose parents were born) in these regions.

There are hundreds of millions of people worldwide who have hepatitis B. Most people don’t even know they are infected, and don’t have symptoms – but there are many important things you should know. Getting tested for hepatitis B can save your life. If you know you have hepatitis B, you can make lifestyle choices to keep your liver healthy and you can see a doctor to help manage the virus and prevent liver damage.

The Hepatitis B Foundation is a national nonprofit organization dedicated to finding a cure and helping to improve the quality of life for all those affected by hepatitis B worldwide through research, education and patient advocacy.

Disclaimer: The information that is provided on this website is for educational purposes only. The Hepatitis B Foundation is not a medical organization. Please talk to your doctor or a qualified health care provider for personal medical care and advice.